Luke 18:15-17

Àwọn ọmọdé àti Jesu

15 aWọ́n sì gbé àwọn ọmọ ọwọ́ tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ rí i, wọ́n ń bá wọn wí. 16Ṣùgbọ́n Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ kékeré wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì ṣe dá wọn lẹ́kun: nítorí tí irú wọn ni ìjọba Ọlọ́run. 17Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbà ìjọba Ọlọ́run bí ọmọ kékeré, kì yóò wọ inú rẹ̀ bí ó ti wù kí ó rí.”

Copyright information for YorBMYO